Judges 18:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin marun-un náà bá kúrò níbẹ̀, wọ́n wá sí Laiṣi, wọ́n sì rí àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀ bí wọ́n ti ń gbé ní àìléwu gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Sidoni tií máa ṣe. Wọ́n ń gbé pọ̀ ní alaafia, kò sí ìjà láàrin wọn, wọ́n ní ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ọrọ̀. Wọ́n rí i bí wọ́n ti jìnnà sí ibi tí àwọn ará Sidoni wà tó, ati pé wọn kò bá ẹnikẹ́ni da nǹkan pọ̀ ní gbogbo àyíká wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin máràrùn náà kúrò, wọ́n sì wá sí Láìsí, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Ṣídónì, láì sí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Ṣídónì, wọn kò fí ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.