Judges 18:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ gbógun tì wọ́n nítorí pé a ti rí ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tí ó lọ́ràá ni. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ẹ má jáfara, ẹ wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ ṣíbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà.