Judges 19:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò tí kò sí ọba ní Israẹli, ọmọ Lefi kan ń gbé apá ibìkan tí ó jìnnà ní agbègbè olókè ti Efuraimu. Ọmọ Lefi yìí ní obinrin kan tí ó jẹ́ ará Bẹtilẹhẹmu ni ilẹ̀ Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati kò sí ọba kan ni Israeli, ọkunrin Lefi kan nṣe atipo ni ìha ọhún ilẹ òke Efraimu, ẹniti o si mú àle kan lati Beti-lehemu-juda wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Ísírẹ́lì kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Léfì tí ń gbé ibi tí ó sápamọ́ nínú àwọn agbégbé òkè Éfúráímù, mú àlè kan láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà.