Judges 19:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jébúsì tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jébúsì kí a sì sùn níbẹ̀.”