Judges 19:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n yà sibẹ, láti sùn di ọjọ́ keji. Wọ́n lọ jókòó ní ààrin ìgboro ìlú náà, nítorí pé, ẹnikẹ́ni kò gbà wọ́n sílé pé kí wọ́n sùn di ọjọ́ keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú náà láti wọ̀ ṣíbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.