Judges 19:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, ọkunrin arúgbó kan ń ti oko bọ̀ ní alẹ́; ará agbègbè olókè Efuraimu ni, ṣugbọn Gibea ni ó ń gbé. Àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini ni wọ́n ń gbé ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Éfúráímù, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gíbíà (ibẹ̀ ni àwọn ènìyàn Bẹ́ńjámínì ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko.