Judges 19:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni a ti ń bọ̀, a sì ń lọ sí ìgbèríko kan ní òpin agbègbè olókè Efuraimu níbi tí mo ti wá. Bẹtilẹhẹmu ti Juda ni mo lọ, mo wá ń pada lọ sílé, nígbà tí a ti dé ìhín, kò sí ẹni tí ó gbà wá sílé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ Léfì náà dá a lóhùn pé, “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà ni àwa ti ń bọ̀, àwa sì ń lọ sí agbégbé tí ó sápamọ́ ní àwọn òkè Éfúráímù níbi ti mo ń gbé. Mo ti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà, èmi sì ń lọ sí ilé OLÚWA nísinsìn yìí. Kò sí ẹni tí ó gbà mí sí ilé rẹ̀.