Judges 19:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń gbádùn ara wọn lọ́wọ́ ni àwọn ọkunrin lásánlàsàn kan aláìníláárí, ará ìlú náà, bá yí gbogbo ilé náà po, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lu ìlẹ̀kùn. Wọ́n sọ fún baba arúgbó tí ó ni ilé náà pé, “Mú ọkunrin tí ó wọ̀ sinu ilé rẹ jáde, kí á lè bá a lòpọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi nwọn ti nṣe ariya, kiyesi i, awọn ọkunrin ilu na, awọn ọmọ Beliali kan, yi ile na ká, nwọn si nlù ilẹkun; nwọn si sọ fun bale ile na ọkunrin arugbo nì, pe, Mú ọkunrin ti o wọ̀ sinu ile rẹ nì wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe àríyá, kíyèsí i, àwọn ọkùnrin ìlú náà, àwọn ọmọ Bélíálì kan, yí ilé náà ká, wọ́n sì ń lu ìlẹ̀kún; wọ́n sì sọ fún baálé ilé náà ọkùnrin arúgbó náà pé, “Mú ọkùnrin tí ó wọ̀ sínú ilé rẹ wá, kí àwa lè mọ̀ ọ́n.”