Judges 19:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Baba arúgbó tí ó ni ilé yìí bá jáde sí wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ wọ́n, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin mi, ẹ má hu irú ìwà burúkú báyìí, ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí wá wọ̀ sinu ilé mi ni, ẹ má hu irú ìwà burúkú yìí sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin, bale ile na si jade tọ̀ wọn lọ, o si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ẹnyin arakunrin mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ má ṣe hùwa buburu; nitoriti ọkunrin yi ti wọ̀ ile mi, ẹ má ṣe hùwa wère yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin, baálé ilé náà sì jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹyin arákùnrin mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ má ṣe hùwà búburú; nítorí tí ọkùnrin yìí ti wọ ilé mi, ẹ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí.