Judges 19:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ní ọmọbinrin kan tí ó jẹ́ wundia, ọkunrin náà sì ní obinrin kan, ẹ jẹ́ kí n mú wọn jáde sí yín nisinsinyii, kí ẹ sì ṣe wọ́n bí ẹ bá ti fẹ́, kí ẹ tẹ́ ìfẹ́ yín lọ́rùn lára wọn, ṣugbọn ẹ má ṣe hu irú ìwà burúkú yìí sí ọkunrin náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ọmọbinrin mi li eyi, wundia, ati àle rẹ̀; awọn li emi o mú jade wá nisisiyi, ki ẹnyin tẹ́ wọn li ogo, ki ẹnyin ṣe si wọn bi o ti tọ́ li oju nyin: ṣugbọn ọkunrin yi ni ki ẹnyin má ṣe hùwa wère yi si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, ọmọbìnrin mi ni èyí, wúndíá, àti àlè rẹ̀; àwọn ni èmi ó mú jáde wá nísinsin yìí, kí ẹ̀yin tẹ̀ wọ́n lógo, kí ẹ̀yin ṣe sí wọn bí ó ti tọ́ lójú yín: ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí ni kí ẹ̀yin má ṣe hùwa òmùgọ̀ yìí sí.”