Judges 19:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ọkunrin náà kọ̀, wọn kò dá a lóhùn. Ó bá ki obinrin ọkunrin náà mọ́lẹ̀, ó tì í sí wọn lóde. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a lòpọ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, wọ́n fi sílẹ̀ pé kí ó máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọkunrin na kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀: ọkunrin na si mú àle rẹ̀, o si mú u tọ̀ wọn wá; nwọn si mọ̀ ọ, nwọn si hù u niwakiwa ni gbogbo oru na, titi o fi di owurọ̀: nigbati o si di afẹmọjumọ́ nwọn jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà kò fetí sí tirẹ̀. Torí náà ọkùnrin náà mú àlè rẹ̀ ó sì tari rẹ̀ jáde sí wọn, wọ́n sì bá a fi ipá lòpọ̀, wọ́n sì fi gbogbo òru náà bá a lòpọ̀, nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́.