Judges 19:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin yìí bá dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ó ṣílẹ̀kùn ilé náà tí ó sì jáde pé kí òun máa lọ, òkú obinrin rẹ̀ ni ó rí, tí ó nà sílẹ̀ gbalaja lẹ́nu ọ̀nà, lẹ́bàá ìlẹ̀kùn, pẹlu ọwọ́ tí ó nà tí ó fẹ́ ṣílẹ̀kùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa rẹ̀ si dide li owurọ̀, o si ṣi ilẹkun ile na, o si jade lati ba ọ̀na rẹ̀ lọ: si kiyesi i obinrin na, àle rẹ̀, ṣubu lulẹ li ẹnu-ilẹkun ile na, ọwọ́ rẹ̀ si wà li ẹnu-ọ̀na na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ jí tí ó sì dìde ní òwúrọ̀ tí ó sì sí ìlẹ̀kùn ilé náà, tí ó sì bọ́ sí òde láti tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, kíyèsí i àlè rẹ̀ wà ní síṣubú ní iwájú ilé, tí ọwọ́ rẹ̀ sì di òpó ẹnu ọ̀nà ibẹ̀ mú,