Judges 19:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkọ rẹ̀ si dide, o si tọ̀ ọ lọ, lati tù u ninu, ati lati mú u pada, ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mbẹ pẹlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ meji: ọmọbinrin na si mú u wá sinu ile baba rẹ̀: nigbati baba rẹ̀ si ri i, o yọ̀ lati pade rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀ tayọ̀ gbà á.