Judges 19:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ijọ́ kẹrin, nwọn jí ni kùtukutu, o si dide lati lọ: baba ọmọbinrin na si wi fun ana rẹ̀ pe, Fi òkele onjẹ kan tẹlẹ inu, lẹhin na ki ẹ ma lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”