Judges 19:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si dide ni kùtukutu ọjọ́ karun lati lọ, baba ọmọbinrin na si wipe, Mo bẹ̀ ọ, tù ara rẹ lara, ki ẹ si duro titi di irọlẹ; awọn mejeji si jẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.