Judges 19:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọkunrin na si dide lati lọ, on, ati àle rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ rẹ̀, ana rẹ̀, baba ọmọbinrin na, si wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ọjọ́ di aṣalẹ tán, emi bẹ̀ ọ duro li oru yi: kiyesi i ọjọ́ lọ tán, sùn sihin, ki inu rẹ ki o le dùn: ni kùtukutu ọla ẹ tète bọ́ si ọ̀na nyin, ki iwọ ki o le lọ ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọlé.”