Judges 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn tí ó kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n ń bọ lára àwọn oriṣa àwọn tí wọ́n yí wọn ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n sì mú inú bí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kọ OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú OLÚWA bínú.