Judges 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì OLÚWA fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀ta wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.