Judges 2:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹsibẹ, wọn kì í gbọ́ ti àwọn aṣiwaju wọn. Wọn a máa sá lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa káàkiri, wọn a sì máa bọ wọ́n. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọ́n á yipada kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba wọn ń rìn. Àwọn baba wọn a máa pa òfin OLUWA mọ́, ṣugbọn ní tiwọn àwọn kì í pa á mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ̀sibẹ nwọn kò fetisi ti awọn onidajọ wọn, nitoriti nwọn ṣe panṣaga tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, nwọn si fi ori wọn balẹ fun wọn: nwọn yipada kánkan kuro li ọ̀na ti awọn baba wọn ti rìn, ni gbigbà ofin OLUWA gbọ́; awọn kò ṣe bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbérè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọràn sí àwọn òfin OLÚWA.