Judges 2:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà inú a bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, a sì wí pé, “Àwọn eniyan wọnyi ti da majẹmu tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba wọn, wọn kò sì fetí sí òfin mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbínú OLÚWA yóò sì tún ru sí Ísírẹ́lì a sì wí pé, “Nítorí tí orílẹ̀-èdè yìí ti yẹ májẹ̀mu tí mo fi lélẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọn kò sì fetí sí mi.