Judges 2:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀ náà, kò tètè lé wọn jáde bí kò ti fún Joṣua lágbára láti ṣẹgun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà OLÚWA fi àwọn orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kò sì lé wọn jáde, tàbí kí ó jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì pa wọ́n run.