Judges 20:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde wá, bẹ̀rẹ̀ láti Dani ní apá ìhà àríwá títí dé Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù ilẹ̀ Israẹli ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi, ní apá ìwọ̀ oòrùn. Wọ́n kó ara wọn jọ sójú kan ṣoṣo níwájú OLUWA ní Misipa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti Dánì dé Bááṣébà, àti láti ilẹ̀ Gílíádì jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ ṣíwájú OLÚWA ni Mísípà.