Judges 20:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdámẹ́wàá àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli yóo máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun, àwọn yòókù yóo lọ jẹ àwọn ará Gibea níyà fún ìwà burúkú tí wọ́n hù ní Israẹli yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ó ò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn ún nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì àti ọgọ́rùn ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gíbíà ti àwọn ará Bẹ́ńjámínì, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”