Judges 20:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.