Judges 20:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?” OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ wọ́n sunkún ní iwájú OLÚWA títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ OLÚWA. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa jà?” OLÚWA dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”