Judges 20:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Benjamini si jade si wọn lati Gibea wa ni ijọ́ keji, nwọn si pa ninu awọn ọmọ Israeli ẹgba mẹsan ọkunrin; gbogbo awọn wọnyi li o nkọ idà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Bẹ́ńjámínì jáde sí wọn láti Gíbíà, láti dojú kọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.