Judges 20:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?” OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni si nduro niwaju rẹ̀ li ọjọ́ wọnni,) wipe, Ki emi ki o ha si tun gbogun jade si Benjamini arakunrin mi bi? tabi ki emi ki o dẹkun? OLUWA si wipe, Ẹ gòke lọ; nitoripe li ọla emi o fi i lé ọ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” OLÚWA dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”