Judges 20:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn Bẹ́ńjámínì ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”