Judges 20:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Olukuluku àwọn ọmọ Israẹli bá kúrò ní ààyè rẹ̀, wọ́n lọ tò ní Baalitamari. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ba ní ibùba bá jáde kúrò níbi tí wọ́n ba sí ní apá ìwọ̀ oòrùn Geba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Báálì Támárì, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọ́n sápamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀ oòrùn Gíbíà.