Judges 20:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá ṣẹgun àwọn ará Bẹnjamini fún àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbẹẹdọgbọn ó lé ọgọrun-un (25,100) eniyan ninu àwọn ará Bẹnjamini lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n pa jẹ́ jagunjagun tí wọn ń lo idà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ṣẹ́gun Bẹ́ńjámínì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbàá méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,000) ọkùnrin Bẹ́ńjámínì, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun.