Judges 20:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Bẹnjamini rí i pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn. Nígbà tí, àwọn ọmọ Israẹli ṣebí ẹni ń sá lọ fún àwọn ara Bẹnjamini, wọ́n ń tàn wọ́n jáde ni, wọ́n sì ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ará wọn tí wọ́n ba ní ibùba yípo Gibea láti gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn. Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì fà sẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gíbíà.