Judges 20:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí èéfín tí àwọn ọmọ ogun Israẹli fi ṣe àmì bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láàrin ìlú, àwọn ará Bẹnjamini wo ẹ̀yìn, wọ́n rí i pé èéfín ti sọ, ó sì ti gba ìlú kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkúukùú ẹ̀ẹ́fín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì yípadà wọ́n sì rí ẹ̀ẹ́fín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run.