Judges 20:43 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láì dáwọ́ dúró bí wọn ti ń lé wọn lọ. Wọ́n pa wọ́n láti Nohahi títí dé iwájú ìlà oòrùn Gibea.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbégbé ìlà oòrùn Gíbíà.