Judges 20:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá yipada, wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ tí ó lọ sí ibi àpáta Rimoni, àwọn ọmọ Israẹli sì tún pa ẹẹdẹgbaata (5,000) ninu wọn ní ojú ọ̀nà. Wọ́n ń lé wọn lọ tete títí dé Gidomu, wọ́n sì tún pa ẹgbaa (2,000) eniyan ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n ṣe síjú padà tí wọ́n sì ń sá lọ sí apá aṣálẹ̀ lọ sí ọ̀nà àpáta Rímónì ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì títí dé Gídómù wọ́n sì tún bi ẹgbàá (2000) ọkùnrin ṣubú.