Judges 20:47 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ninu wọn sá lọ sí apá aṣálẹ̀, síbi àpáta Rimoni, wọ́n sì ń gbé inú àpáta Rimoni náà fún oṣù mẹrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹgbẹta ọkunrin yipada, nwọn si sá si ìha ijù si ibi okuta Rimmoni, nwọn si joko sinu okuta Rimmoni li oṣù mẹrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rámónù, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin.