Judges 20:48 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli bá yipada sí àwọn ará Bẹnjamini, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá fojú kàn, ati eniyan ati ẹranko. Gbogbo ìlú wọn tí wọ́n rí ni wọ́n sì sun níná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli si pada tọ̀ awọn ọmọ Benjamini, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu, ati ẹran, ati ohun gbogbo ti nwọn ní: gbogbo ilu ti nwọn ri ni nwọn fi iná kun pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì padà sí àwọn ìlú Bẹ́ńjámínì wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.