Judges 20:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá gbé òkú rẹ̀, mo gé e lékìrí lékìrí, mo bá fi ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ Israẹli jákèjádò, nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti ṣe nǹkan burúkú ati ohun ìríra ní Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí-ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbégbé ìní Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.