Judges 21:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìjọ eniyan náà bá rán ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn jagunjagun wọn tí wọ́n gbójú jùlọ, wọ́n sì fún wọn láṣẹ pé, “Ẹ lọ fi idà pa gbogbo àwọn tí ń gbé Jabeṣi Gileadi ati obinrin wọn, ati àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọ si rán ẹgbã mẹfa ọkunrin ninu awọn akọni sibẹ̀, nwọn si fi aṣẹ fun wọn pe, Ẹ lọ ẹ si fi oju idà kọlù awọn ara Jabeṣi-gileadi, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹrẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gílíádì wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.