Judges 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n rí irinwo (400) ọdọmọbinrin tí kò tíì mọ ọkunrin lára àwọn tí wọn ń gbé ìlú Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì kó wọn wá sí àgọ́ ní Ṣilo, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n rí àwọn irinwó (400) ọ̀dọ́bìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí nínú àwọn olùgbé Jabesi-Gílíádì, wọ́n sì mú wọn lọ sí ibùdó ní Ṣílò àwọn ará Kénánì.