Judges 21:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn sibẹsibẹ, a kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọ wa fún wọn.” Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti búra pé, “Ẹni ègún ni ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọmọ fún ará Bẹnjamini.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awa kò lè fi aya fun wọn ninu awọn ọmọbinrin wa: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti bura, wipe, Egún ni fun ẹniti o ba fi aya fun Benjamini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe ìbúra yìí pé: ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.’ ”