Judges 21:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Bẹnjamini bá ṣe bí wọ́n ti sọ fún wọn. Olukuluku wọn gbé obinrin kọ̀ọ̀kan sá lọ ninu àwọn tí wọ́n wá jó, gbogbo wọn sì pada lọ sí ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ìlú wọn kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.