Judges 21:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n wí pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí irú èyí fi ṣẹlẹ̀ ní Israẹli, tí ó fi jẹ́ pé lónìí ẹ̀yà Israẹli dín kan?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sunkún wí pé, “Háà! OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, èéṣe tí nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì? Èéṣe tí ẹ̀yà kan yóò fi run nínú Ísírẹ́lì lónìí?”