Judges 3:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. Ó jáde lọ sí ojú ogun, OLUWA sì fi Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹgun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹmi OLUWA si wà lara rẹ̀, on si ṣe idajọ Israeli, o si jade ogun, OLUWA si fi Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia lé e lọwọ: ọwọ́ rẹ̀ si bori Kuṣani-riṣataimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀mí OLÚWA bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. OLÚWA sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.