Judges 3:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu, lágbára lórí wọn, nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti o buru loju OLUWA: OLUWA si fi agbara fun Egloni ọba Moabu si Israeli, nitoripe nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú OLÚWA, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí. OLÚWA fún Égílónì, ọba àwọn Móábù ní agbára ní orí Ísírẹ́lì.