Judges 3:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí wọ́n tún ké pe OLUWA, OLUWA gbé olùdáǹdè kan, ọlọ́wọ́ òsì, dìde, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ehudu, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini. Ní àkókò kan àwọn ọmọ Israẹli fi ìṣákọ́lẹ̀ rán an sí Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ Israeli kigbepè OLUWA, OLUWA si gbé olugbala kan dide fun wọn, Ehudu ọmọ Gera, ẹ̀ya Benjamini, ọlọwọ́-òsi: awọn ọmọ Israeli si fi ẹ̀bun rán a si Egloni ọba Moabu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì tún ké pe OLÚWA, OLÚWA rán olùgbàlà sí wọn, Éhúdù ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gérà ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Éhúdù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi owó orí wọn rán sí Égílónì olú ìlú Móábù ní ọdọọdún fún ọdún mẹ́rìndínlógún.