Judges 3:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí pé OLUWA ti fi àwọn ará Moabu, tíí ṣe ọ̀tá yín le yín lọ́wọ́.” Wọ́n bá ń tẹ̀lé e lọ, wọ́n gba ibi tí ó ṣe é fi ẹsẹ̀ là kọjá níbi odò Jọdani mọ́ àwọn ará Moabu lọ́wọ́, wọn kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun wọn pe, Ẹ ma tọ̀ mi lẹhin: nitoriti OLUWA ti fi awọn ọtá nyin awọn ara Moabu lé nyin lọwọ. Nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ, nwọn si gbà ìwọdo Jordani, ti o wà ni ìha Moabu, nwọn kò si jẹ ki ẹnikan ki o kọja mọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí OLÚWA ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.