Judges 3:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aṣiwaju tí ó tún dìde lẹ́yìn Ehudu ni Ṣamgari, ọmọ Anati, ẹni tí ó fi ọ̀pá tí wọ́n fi ń da mààlúù pa ẹgbẹta (600) ninu àwọn ará Filistia; òun náà gba Israẹli kalẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin rẹ̀ ni Ṣamgari ọmọ Anati, ẹniti o fi ọpá ti a fi ndà akọmalu pa ẹgbẹta ọkunrin ninu awọn ara Filistini, on pẹlu si gbà Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn Éhúdù, ni ṣáḿgárì ọmọ Ánátì ẹni tí ó pa ọgọ́rùn ún mẹ́fà Fílístínì pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Ísírẹ́lì kúrò nínú ìpọ́njú.