Judges 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori na ibinu OLUWA ru si Israeli, o si tà wọn si ọwọ́ Kuṣani-riṣataimu ọba Mesopotamia: awọn ọmọ Israeli si sìn Kuṣani-riṣataimu li ọdún mẹjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbínú OLÚWA sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.