Judges 4:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò yìí, Heberi ará Keni ti kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ará Keni yòókù tí wọ́n jẹ́ ìran Hobabu, àna Mose, ó sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Kedeṣi lẹ́bàá igi oaku kan ní Saananimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì (àwọn ẹ̀yà Kénì jẹ́ ìran Hóbábù ẹni tí i ṣe àna Móṣè).