Judges 4:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Debora wí fún Baraki pé, “Dìde nítorí pé òní ni ọjọ́ tí OLUWA yóo fi Sisera lé ọ lọ́wọ́. Ṣebí OLUWA ni ó ń ṣáájú ogun rẹ lọ?” Baraki bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Tabori pẹlu ẹgbaarun (10,000) ọmọ ogun lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, “Lọ! Lónìí ni OLÚWA fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, OLÚWA ti lọ ṣíwájú rẹ.” Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì.